Lagbala iroyin la ti gbo pe egbe oniroyin nipinle Osun, Nigeria Union of Journalists (NUJ), ti dawoodunnu pelu gbajugbaja olorin nni, Ogbeni Gbenga Falope Jr lori iyansipo re laipe yii gege bi aare egbe awon olorin lorileede yii, iyen Preforming Musician Association of Nigeria (PMAN).
Ninu atejade kan ti alaga egbe naa, Abiodun Olalere ati akowe, Bamigbola Boladale fi sita ni won ti sapejuwe iyansipo Falope gege bii ika to to simu ti won fi re e.
Egbe naa ni yato si ipa aderinposonu ti orin Falope Jr n ko ninu aye awon eeyan nibikibi to ba ti sere, o tun je orisun iwuri fun opolopo eeyan nipinle Osun.
Bakan naa ni won gboriyin fun Falope pelu bo se n ko ipa tire lati pese ise fawon odo kaakiri ipinle Osun ti opolopo si n ri ounje oojo je labe egbe re.
Gege bi won se wi, "ipo yii yoo tubo fi ipinle Osun han gege bii ipinle awon omoluabi ti won kii se imele ninu idawole won, bee ni yoo si mu isokan wa ninu egbe PMAN siwaju sii."
Egbe oniroyin Osun waa seleri ibasepo to tun dan monran sii laarin egbe naa ati Gbenga Falope Jr.
No comments:
Post a Comment