Lagbala iroyin la ti gbo pe adajo majisreeti kan nipinle Eko ti pase pe ki omokunrin eni odun meedogbon kan, Benjamin Akegh loo faso penpe roko oba fun odun kan gbako lori esun ole jija.
Lasiko ti isin irole n lo lowo ninu ijo Redeemed Christian Church of God, Tabernacle of Peace lagbegbe Oluwole Baker, Thomas Estate, Ajiwe, lojo ketadinlogbon osu kinni odun yii la gbo pe olujejo huwa naa.
Benjamen, eni to sese ti ewon de lori esun ole jija kannaa la gbo pe o ti tu telifisan alademogiri ti owo re je egberun lona ogoji naira to si je ti Pasito Ayodeji Adeniyi ni nnkan aago mejo ale ojo naa ko too di pe ara ijo kan ka a mobe.
Ispekito Philip Osijale so ni kootu pe Benjamin ti n sa lo lojo naa ki owo awon araadugbo to te e ti won si fa a le awon olopa lowo.
Leyin ti olujejo so pe oun jebi esun naa ladajọ majisreeti ohun, L.O. Kazeem pase pe ko loo sewon odun kan gbako.
No comments:
Post a Comment