Lati aye yii ni mo ti fe kawọn oluko jere ise won - Onorebu Olatunji
Lati le se koriya fawon oluko ti won n sise nijoba ibile Ariwa Ife, Onorebu Tunde Olatunji to n soju agbegbe naa nile igbimo asofin ti gbe eto awoodu kan kale bayii.
Awoodu naa to pe ni Babatunde Olatunji Education Awards and Mentorship Programme lo wa fun oluko to ba pegede julo ni ipele kilaasi meteeta to wa l'Osun bayii, iyen Best High School Teacher, Best Middle School Teacher ati Best Elementary School Teacher.
Gege bi Olatunji se ba lagbala iroyin so, ipa ribiribi ti awon oluko nko lori aye awon akeko lati muraa won sile fun ojo iwaju to logo ye ni eyi to ye ki gbogbo eeyan maa gbosuba fun won le lori.
Bakan naa ni ami eye tun wa fun awon akeko okunrin ati obinrin ti won ba gbounje fegbe gbawo bo nileewe ijoba lagbegbe naa.
Aadoje oluko ati akeko ni won yoo janfaani awoodu naa eleyii ti yoo waye losu keta odun yii leyin ti awon eekan ninu eto eko l'Ariwa Ife ba ti mu awon ti won ba yege laifi ti eya, esin tabi egbe oselu se.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment