Wahala inu egbe oselu APC nipinlẹ Kaduna tun ba ona miin yo loni nigba ti awon asaaju abala kan ninu egbe naa ni ki gomina Ipinle ohun, Mallam Nasir El Rufai lo sinmi osu mefa nile.
Awon eeyan ohun ti Senator Hunkuyi ko sodi so pe igbese naa ko seyin bi gomina se kuna lati fesi si awon esun ti won fi kan an ninuu leta kan ti won ko sii lojo meta seyin.
A oo ranti pe awon abala kan ni won koko da Senator Hunkuyi duro fosimefa, ti won si fowo osi juwe ile fawon mejidinlogbon miin.
Sugbon alaga abala keji, Alhaji Danladi Wada ni igbimo olulaja ti Asiwaju Bola Tinubu ko sodo le ma ri nnkan kan se nipinle Kaduna ti Mallam El Rufai ko ba tete tuuba awon iwa to hu.
No comments:
Post a Comment