Kaadi idibo nikan ni agbara ti awa odo ni l'Osun - Olorungbebe Adunni

Alakoso egbe odo kan ninu egbe  oselu APC nipinle Osun, Osun All Progressives Youth Forum (OAPYF), Komureedi Olateju Olorungbebe Adunni ti ro gbogbo awon odo ipinle yii lati gba kaadi idibo,  ki won si toju e daada.




Lasiko itaniji ti egbe naa n se kaakiri ekun idibo ijoba apapo mokookanla to wa l'Osun ni Olateju ti ni agbara kansoso tawon odo ni  fun Itesiwaju ijoba alakoyawo ti Gomina Aregbesọla n se ni ki won gba kaadi idibo won ko too di asiko idibo.

Gege bo se wi, erongba egbe OAPYF ni lati petu si okan gbogbo awon omo egbe oselu APC ti won ba ni ikunsinu kan tabi omiin, ki won si wa ona bi alaafia yoo se wa ninu egbe ko too di asiko idibo .


Nigba ti won de agbegbe Irewole, Isokan ati Ayedaade, Olateju ni ona kansoso tawọn odo fi le lanfaani lati dibo fun enikeni to ba wu won ni ki won gba kaadi idibo won, ki won si toju e.

Ninu oro ti komisanna feto isuna, Onorebu Bola Oyebamiji seleri fun ogunlogo awon eeyan ti won wa nibe pe laipe yii ni Gomina Aregbesola yoo bere sii san ekunrere owo osu fawon osise ijoba.

O ni gomina ko sinmi rara, ojoojumo lo n gbe oniruuru igbese lati mu ki oro aje ipinle Osun rugogo sii.

Bakan naa ni komisanna foro ijoba ibile, Kolapo Alimi ati komisanna foro okoowo, Alagbada Jayeoba pelu Komisanna foro sayensi ati Imo ero, Remi Omowaye ro gbogbo awon odo nipinle Osun lati fowosowopo pelu Gomina Aregbesola funtesiwaju ipinle Osun.

No comments:

Post a Comment