Se ogun laye ni? Obasi pin ada ati ọkọ fawon iya agbalagba, o ni erejẹ demokrasi ni


Asofin to n soju awon eeyan Ariwa Ohafia nile igbimo asofin ipinle Abia, Onorebu Mandela Obasi ti pin opolopo ada ati oko fawon eeyan agbegbe re gege bi ona lati gbe agbara wo won.






Obasi,  eni to je omo egbe oselu PDP ni awon ebun naa je ara ere ijoba tiwantiwa toun seto fawon eeyan oun.

Ohun to je ijoloju ninu igbese asofin yii ni pe awon iya agbalagba lo ko jo, to si pin awon ada UTC naa fun.

O ni se loun fe ki awon iya agbalagba naa maa wa nnkan se, ki won yee rogboku le ijoba.

No comments:

Post a Comment