Ijoba apapo nikan lo le fopin si wahala awon fulani darandaran - Mudashiru Toogun
Ti wahala ipaniyan awon fulani darandaran yoo ba rokun igbagbe lorileede yii, afi kijoba apapo ba awon lookolooko nidi osin maalu so ohun to n je ooto oro.
Komisanna foro akanse ise nipinle Osun, to tun je alaga tijoba Aregbesola gbe kale lori oro ipetusaawo laarin Fulani atawon agbe, Onorebu Mudashiru Toogun lo si aso loju oro yii lagbala iroyin .
Toogun ni kii se awon fulani gan an ni won ni awon maalu ti won n ko je oko awon agbe yii bikose awon eeyan nlanla lawujo wa.
O ni awon eeyan yii, bii awon oga agba olopa, awon seneto, awon olori orileede tele ati bee bee lo ni Aare Buhari gbodo ba sepade to nitumo.
Bee ni Toogun ni ijoba apapo gbodo gbe agbara wo awon agbofinro ki won le sise won bii ise .
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment