Ko si ireti fegbe PDP l'Osun bi Omisore ko ba dije funpo gomina- OMT


Lagbala iroyin la ti gbo pe ko si ooto ninu aheso to n lo kaakiri bayii pe igbakeji gomina tele nipinle Osun, Otunba Iyiola Omisore ti so pe oun ko dupo gomina mo.



Gege bi atejade kan ti egbe Omisore Media Team gbe jade se wi, ohun to daju saka to si duro bii oke ni ipinnu Omisore lati di gomina ipinle Osun lojo kejilelogun osu kesan odun yii.

Atejade ohun ni inu Omisore nikan ni ireti awon eeyan ipinle Osun wa lati gba won lowo ise ati gbese tisejoba Gomina Aregbesola ko won si ati pe bi Omisore ko ba dupo labe PDP, a je pe egbe naa n lo sokun igbagbe l'Osun niyen.

OMT ni iro patapata to wa latodo awon agbesunmomi ni aheso naa ati pe ko si ibi kankan ti Omisore ti so pe oun ko dupo mo, bee ni ko gbe igbese kankan to le toka si eleyii.

Egbe naa wa ro gbogbo awon oludibo l'Osun lati dibo fegbe PDP lasiko idibo gomina to n bo yii.

No comments:

Post a Comment