Lagbala iroyin la ti gbo pe ti kii ba se aanu Olorun, ajalu nla mi-in iba tun sele lagbo awon osere tiata Yoruba wa, pelu bi okan ninu won, Adekunle Ayanfe tawon eeyan mo si Aafa Monsuru yo ninu ijamba moto.
Gege bi a se gbo, oko ere losere apanilerin-in naa n lo ti moto jiipu to wa ninu e nijamba, ti gbogbo iwaju oko naa si run, bee ni Ayanfe naa fi oju osi e se se, ile iwosan lokunrin naa wa to ti n gbatoju lowolowo bi a se n koroyin yii.
No comments:
Post a Comment