L'Ekiti, awon bororo sa olokada pa, lawon ode-ilu ba fariga


Ti dugbedugbe to n fi loke bayii nilu Ekiti ba ja, opolopo awon ti ko mowo-mese ni yoo faragba nibe.



Eleyii ko seyin bi awon Fulani darandaran tawon eeyan tun mo si bororo se sa okunrin olokada kan pa losan ojoo isinmi to koja.

Omo ilu Ipao Ekiti nijoba ibile Ikole ni Olayemi Tunde to je omo odun mejilelogbon, oun pelu enikan ni won si jo lo sibi oko ege to gbin sigbo oba to wa nilu naa.

Bi won se n bo lori okada lawon bororo ohun dede yo si won pelu ibon, bi won se n salo lawon fulani naa mu Tunde, won si sa a yannayanna.

Idi niyii tawon ode ilu naa se waa leri ogun pelu awon Fulani darandaran bayii pe awon ko nii gba afi tawon ba gbesan.

No comments:

Post a Comment