O maa soro fun egbe oselu miin lati gbajoba lowo Aregbesola - Abiodun Layonu
Lagbala iroyin la ti gbo pe okan pataki lara awon ti won n fojusona lati dupo gomina ipinle Osun labe asia egbe APC, Dokita Saka Abiodun Layonu ti so gbangba pe ajanaku ni awon ise ribiribi ti Gomina Aregbesola ti gbe se l'Osun, kii se eru omode rara.
Lasiko ti okunrin oloselu to tun je Aagbejoro agba lorileede yii pe apeje lati ba awon Kanselo ti won sese diboyan ni gbogbo woodu to wa nilu Ede dawoodunnu lo ti ni itanje nikan ni bi egbe oselu miin yato si APC ba n gbero lati gba eeku ida lowo Aregbesola.
Layonu ni ko si eka kankan tisejoba Aregbesola ko fowokan laarin odun to ti lo l'Osun ati pe o han lara awon araalu gan an pe isejoba to mu igbeaye irorun araalu lokunkundun nisejoba APC.
O waa ro awon eeyan ipinle Osun lati mase faaye gba ohunkohun to le pagidina awon erongba rere Gomina Aregbesola l'Osun, ki won si fowosowopo pelu re lati saseyori.
Bakan naa ni Dokita Layonu, eni ti opolopo tomodetagba nilu Ede pe wamuwamu silee re ro awon Kanselo tuntun lati mase ja awon araalu kule ninu igbekele ti won ni ninuu won ti won fi dibo fun won.
O ni won gbodo mu igbayegbadun awon araalu lokunkundun, ki won si rii pe won mu ereje ijoba tiwantiwa de origun mereerin ilu Ede.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment