Osun 2018: "Erongba Oyinlola yoo di mimo laipe"
Pelu bi aheso se n lo kaakiri bayi lorii boya gomina tele nipinle Osun, Omooba Olagunsoye Oyinlola n gbero lati tun dupo gomina tabi bee ko, arigbamu iroyin ti fidi re mule bayii pe laipe ni Oyinlola funraare yoo soro nipa aheso naa.
Okan lara awon alatele Oyinlola ninu oselu salaye fun wa lagbala iroyin pe looto ni oniruuru ipade ti n lo l'Okuku to je ilu abinibi okunrin oloselu naa sugbon Oyinlola funraare ko tii so ohun to fe se.
Eni naa, to ni ka foruko bo oun lasiri ni gbogbo bi nnkan se n lo ni Oyinlola n so fawon omoleyin re ninu oselu ati pe aimoye awon lookolooko ni won n lo ba Oyinlola lati dije labe egbe oselu lorisirisi.
O ni nibi ipade tawon se gbeyin ni Oyinlola ti fun awon ni gbedeke ose meta lati loo Romu lori igbese to ye koun gbe; yala lati dije funpo gomina Osun ni tabi lati di babaasale ninu oselu.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment