Lagbala iroyin la ti gbo pe omokunrin kan toruko re n je Moshood ti gun ore re pa lasiko ti awuyewuye kan be sile laarin won lori egberun kan naira ti won ri he leba ona.
Agbegbe Makoko ni Yaba nipinle Eko nisele naa ti sele.
Awon mejeeji la gbo pe won jo wa papo nigba ti won ri owo naa sugbon ariyanjiyan be sile lori eni to koko ri owo naa, ko si pe ti esu fi ba won da si oro naa, Moshood si fi obe gun ore re lorun.
Oro naa ko si pe rara ti ore re fi jade laye. Bayi lawon odo agbegbe ya lu Moshood, won na an bii kiku bii yiye ki won to fa le awon olopa lowo.
No comments:
Post a Comment