Oluwo gbodo ko bi ori-ade se maa n huwa lawujo olaju - Ogundokun

Lagbala iroyin la ti gbo pe asiwaju kan nilu Iwo, Oloye Abiola Ogundokun ti ke si gbogbo awọn lookolooko nile Yoruba lati fa Oluwo tilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi leti lati deyin ninu sisoro alufansa si Ooni tilu Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi.


Ninu atejade kan ti Ogundokun fowosi, o sapejuwe iwa ti Oluwo n hu si Ooni gege bii iwa ara-oko, aibowo fun ite Ooni ati iwa sekarimi eleyii to tako iwa irele ti won ml ilu Iwo mo.

Eleyii ko seyin bi Oluwo se so laipe yii pe eso Ooni fowo ro oun seyin nibi ipade awon lobaloba, iyen National Traditional Rulers Council of Nigeria (NTRCN) to waye nilu Port Harcourt.

Ogundokun ni kii se igba akooko niyen ti Oluwo maa huwa naa si Ooni, o waa ro Ooni, "gege bii eni to jade lati ile rere" lati de fila 'ma wobe' si awon iwa ailolaju ti Oluwo n hu sii".

O ni kaakiri agbaye ni won ti n gboriyin fun Ooni pelu ipa to n ko nidi bi eya Yoruba yoo se wa nisokan, idi niyii to fi ni ko gbodo wo ariwo oja to le di lowo rara.

No comments:

Post a Comment