"Ahesọ lasan ni o, ko si nnkan to se Oba Aromolaran o"
Awon ti won sun mọ Owa Obokun Ile Ijesa, Oba Adekunle Aromoran ti so pe ko si ooto ninu aheso kan to n lo kaakiri pe ọba naa ti waja.
Gege bi a se gbo, kabiesi naa lo silu London logunjo osu kewa odun yii, o si ti pada de silu Eko lojoo fraide to koja, koda o ba awon kan soro lorii foonu laaro oni.
Iwadi fi han pe ninu ose yii ni oba naa yoo pada silu Ilesa.
No comments:
Post a Comment