Ọlọpọlọ pipe to ni ifẹ awọn araalu lọkan ni Ọmọworarẹ - Famurewa

iroyin/oselu


Asofin to n soju awon eeyan ẹkun Gusu Ijesa (Ijesa South Federal Constituency) nile igbimo asofin apapo orileede yii, Onorebu Ajibola Famurewa ti sapejuwe Seneto Babajide Omoworare gege bii oloselu to mo nnkan to n se.

Ninu oro ikini ku oriire ayajo aadota odun to ti de oke eepẹ, eleyii ti Famurewa fi ranse si Omoworare, o ni oloselu to je olopolo pipe, to si se e mu yangan ni Omoworare.

Famurewa fi kun oro re pe aimoye idagbasoke ni iriri Omoworare, eni to n soju awon eeyan Ife/Ijesa nile igbimo asofin agba orileede yii ti mu ba awon eeyan agbegbe to n soju ati ipinle Osun lapapo.

O ni ipa manigbagbe ni Seneto Omoworare ti ko ninu igbe aye awon araalu, bee si ni itan ko lee gbagbe rẹ laelae fun awon ise rere to se lodun mejo to lo nile igbimo asofin agba.

Famurewa, eni to nireti lati gba ipo ile igbimo asofin agba Ife/Ijesa lowo Omoworare gbadura fun emi gigun pelu ilera pipe fun asofin naa.

No comments:

Post a Comment