Iwadi ti fidi re mule bayii pe omobibi ilu Iwo lomobinrin ti won ni o fee lu Oluwo, Oba Adewale Akanbi ni jibiti.
Agbala iroyin gbo pe kii se igba akooko niyen ti yoo maa puro gbowo ka. Se lo si pe ara re ni okan lara awon omoobabinrin Alaafin tilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi nigba to de odo Oluwo laaro oni, fraide.
Nigba ti Oluwo pe Oba Adeyemi lorii foonu ni asiri tu pe kabiesi yii ko ran enikeni si Oluwo.
Amo sa, leyin iwadi ni won rii pe omobibi ilu Iwo lobinrin pupa to ti bora tan ohun. Oluwo si ti setan lati wa nnkan se si oro obinrin naa.
No comments:
Post a Comment