Minista fun eto iroyin lorilẹede yii, Alhaji Lai Mohammed ti so pe iro to jinna soooto ni iroyin to n lo kaakiri pe oun dunkoko mo orileede Isreal lori oro Nnamdi Kanu.
Lai ni ilu London loun wa nigba toun gbo pe won ti ri Kanu ni orileede Isreal, oun ko si lanfaani lati so nnkan kan lori e nibe.
Sugbon iyalenu lo je fun oun lati maa ka a lori ero ayelujara pe oun hale mọ orileede Isreal pe won yoo ri pupa oju ijoba orileede yii ti won ko ba fi ọwọ taari Kanu pada si Naijiria.
O ni iroyin ẹlẹjẹ lasan ni, oun ko sọ nnkan to jọ bee rara.
No comments:
Post a Comment