Adeoti, eni to n dije labe asia egbe oselu ADP soro yii nibi ipolongo ibo to waye nilu Iwo loni.
O ni oun ko se e fowo ro seyin rara ti a ba n so nipa mimọ ibi ti bata ti n ta awon araalu lese nitori oun ti se kanselo ri, bee loun ti figba kan ri je alaga ijoba ibile.
Adeoti salaye fun awon obitibiti ero ti won pejọ sibe pe ipa ti oun ko lasiko ti oun je alaga fegbe oselu AC to gbe Gomina Aregbesola wole ko see foju fo da.
Idi niyii ti Adeoti fi ro gbogbo awon eeyan ipinle Osun lati fi ibo won gbe oun wole lojo kejilelogun osu kesan odun yii.
O ni oun ti setan lati satunse awon kudiekudie to farahan ninu isejoba to n kogba wọle yii nitori pe gbogbo igbesi aye oun loun lo pelu awon eeyan ipinle Osun.
Lara awon ti won tun soro nibi ipolongo ibo naa ni Alhaji Bayo Salami, eni to ro awon eeyan lati dibo won fun egbe ADP nitori eni to mona lo ye ka tele.
Bakan naa ni Oluomo Sunday Akere fi da awon eeyan ipinle Osun loju pe won ko nii kabamo ti won ba dibo won fun Adeoti nitori oniruuru eto igbayegbadun lo ni fun awon araalu.
No comments:
Post a Comment