Idi ti Gboyega Oyetola fi tayọ awon oludije funpo gomina to ku - Akinnaso

Onwoye oselu ipinle Osun kan, Niyi Akinnaso ti so pe bi igiimu se jinna sagbari ni Alhaji Gboyega Oyetola ti egbe APC jinna si awon oludije funpo gomina to ku ti a ba n so nipa iriri, imo iwe ati iwa omoluabi.

Ninu apileko kan ni Akinnaso ti woye oro yii. O ni pelu awon oniruuru iwadi ti oun ti se nipa idibo yii, aarin egbe oselu APC ati PDP ni idije naa wa bo tile je pe egbe oselu marun ṣa-n-ko-ṣa-n-ko ni won wa ninu awon egbe bii mejidinlaadota ti won foruko sile lodo ajo INEC.

O ni "Leyin idibo abele to ni akoyawo ni Gboyega Oyetola di oludije fun egbe APC, inagije eto ipolongo re to pe ni 'Ileri Oluwa' kii si se lasan, o jinle pupo. Loooto la le so pe awon oludije marun pataki wa lara awon ti INEC gbe oruko won jade, iyen Oyetola (APC); Demola Adeleke (Peoples Democratic Party); Iyiola Omisore (Social Democratic Party); Moshood Adeoti (Action Democratic Party); ati Fatai Akinbade (African Democratic Congress), sugbon teeyan ba wo bi egbe oselu won se milẹ si, o dabi eni pe aarin egbe APC ati PDP ni idije yii wa. 

"Okookan awon oludije yii ni won ni agbara ati kudiekudie, sugbon Oyetola yọ loke tente laarin won. Lakooko, oun nikan lo ni amuye to ga julo nipa eto ẹkọ; oye to jinle nipa ọrọ inawo, o si tun ni iriri lopolopo nipa isejoba ipinle Osun.

"O ti sise nipo oga lopolopo awon ileese adojutofo nlanla ko too di pe o da ileese aladani tie sile, idi niyii to fi rorun fun un lati le yọ ipinle Osun ninu ijamba ti eto oro aje to denukole lagbaye mu ba a.

"O mo si bijoba se n san owo osu awon osise, paapaa, nigba to dabi eni pe o ye kijoba da awon osise duro, won jo se adehun bi won yoo se maa gbowo, o si tun wa lara bi owo osu sisan se pada di odidi, eleyii to si ti seleri lati maa te siwaju ninu e to ba ti di gomina ipinle Osun.

"Eleekeji, Oyetola, gege bii olori osise loofiisi gomina fun odidi odun mejo, ti mo nipa amuse awon ẹga mefa tisejoba Gomina Aregbesola pin si, idi niyii to fi kun oju osuwon lati gbapo lowo Aregbesola fun itesiwaju awon ise ribiribi yii.

"Lara awon amuse yii ni ipese ounje ofe fawon omooleewe, fifun won ni aso ileewe lofee, kiko awon ileewe awosifila to kun fun awon irinse ikowe ati sise idanilekoo loorekoore fun awon oluko ti won n ko awon omo ni imo ede oyinbo ati ti isiro.

"Gbogbo aseyori Gomina Aregbesola, eni tawon olooto eeyan sapejuwe gege bii gomina to se daadaa julo lorileede yii, nidi eto ilera to peye ati ona baba ona nilo olopolo pipe bii tie lati te siwaju ninu e. 

"Oyetola nikan ni eto ipolongo ibo re duro lorii titesiwaju ninu awon ise akanse ati eto amayederun ti awon araalu, nile ati leyin odi, n kan sara si bayii, se lawon oludije to ku n so pe awon yoo da ọwọ ise rere yii duro tawon ba debẹ.

"Eleeketa, Oyetola je eni to see fokantan ati olotito eeyan, o ni iwa abinibi to see mu yangan lawujo, pelu erin lo fi maa n yanju oro to ba wuwo, bee ni kii se laulau lori ohunkohun. Kii ṣekuṣẹyẹ ninu oselu, ko kuro ninu egbe onitesiwaju ri, idi si niyii tawon asaaju ati omoleyin re ninu oselu fi maa n pe e ni omo egbe to je oloooto.

"Oyetola le ma safihan gbogbo awon amuye ti mo la kale yii lasiko itakuroso laarin awon oludije to waye laipe, sugbon o dahun gbogbo ibeere ti won beere lowo e pelu otito inu, o si safihan eni to lafojusun rere fawon eeyan ipinle Osun.

"Nitori idi eyi, lemi naa se fi idunnu mi han lati so pe Gboyega Oyetola lo tọ, to si yẹ kawon araalu dibo fun gege bii gomina lojo satide, ojo kejilelogun osu kesan odun yii".

No comments:

Post a Comment