Laipe nipinle Osun yoo di ibudo ipese ounje lorileede yii - Ayodele Lawal


Enjinia Ayoade Lawal ti fọwọ re sọya pe laipe ni gbogbo awon ipinle to wa lorileede Naijiria yoo bere sii rogboku le awon agbe ipinle Osun fun ipese ounje.



Lawal, eni to ti fife han lati dije funpo gomins ipinle Osun labe asia egbe oselu APC salaye pe ti oun ba le lanfaani lati de ipo naa, oun yoo ro awon agbe lagbara pelu awon irinse idako igbalode lati le mu ki ounje po yanturu.

O ni ile to kun fun wara ati oyin ni Olorun fi jinki awon eeyan ipinle Osun, ko si si eso tawon agbe gbin ti ko nii gbile, ohun tawon agbe kan nilo ni koriya, eleyii lo ni yoo mu ki won fi gbogbo ara sise, ti ise agbe yoo si maa wu awon odo lati ya si.

Yato si oro ise agbe, Ayodele Lawal seleri lati te siwaju nibi ti Gomina Aregbesola ba ise de nipinle Osun nitori opolopo awon nnkan ara meriiri nijoba to n lo yii ti se fundagbasoke ipinle Osun.

O ni gbogbo awon ise akanse tijoba Aregbesola n se lowolowo loun yoo pari ni kete toun ba ti de ori aleefa, bee loun naa yoo dawole awon ise idagbasoke loniruuru kaakiri ipinle Osun.

Gege bo se so, Aregbesola ti se takuntakun nipinle Osun eleyii ti ko tii si iru e ri, idi si niyii ti oun fi pinnu pe koun naa lo ogbon ati anfaani ti Olorun fun oun lati se asekun awon ise naa.

O ni bi awon nnkan wonyii yoo ba se e se, ipinle Osun nilo awon ileese keekeke ati nlanla nibi ti oke aimoye awon araalu yoo ti maa ri ise se laifi ti oselu se, oun si ti bere igbese lori eleyii, yoo si wa si imuse ni kete toun ba ti de ori aleefa gege bii gomina ipinle Osun.

Enjinia yii fi kun oro re pe ijoba oun yoo tun pese ise nipase awon ibudo asa atawon nnkan isenbaye lorisiirisii ti Olorun fi da ipinle lola.

Ni ti eto aabo, Lawal ni ju bo se wa lowolowo yii lo, aabo emi ati dukia awon eeyan ipinle Osun yoo je isejoba oun logun, bee lawon araalu yoo tubo maa gbadun ise awon agbofinro siwaju sii.

O waa ro awon asoju ninu egbe oselu APC lati fi ibo won gbe oun wole gege bii oludije funpo gomina latinu egbe APC, ati kawon eeyan ipinle Osun faaye gba oun lati sin won.

No comments:

Post a Comment