Idi ti a fi kuro ninu egbe oselu SDP l'Osun - Awon Koseemani


Oke aimoye awon omo egbe oselu Social Democratic Party (SDP) nipinle Osun ni won ti digba-dagbon won bayii nimurasile lati darapo mo egbe oselu PDP.

Awon oloselu ti won ti laami-laaka lagbegbe won ohun ni won pe ara won ni Koseemani Group, won si je ida ogorin ninu ogorun-un awon omo egbe SDP nipinle yii.

Awon eeyan yii ni won pawopo di ibo to le legberun lona aadofa fun Otunba Iyiola Omisore labe abe SDP lasiko idibo gomina to waye koja l'Osun.

Sugbon ni bayii, latari ohun ti won sapejuwe gege bii iwa imotara-eni nikan ati ijora-eni loju ti oludije ipo gomina fegbe naa n hu si won, won pinnu lati darapo mo egbe oselu PDP.

Lasiko ipade itagbangba egbe PDP niha Iwo-oorun Guusu orileede yii, eleyii ti yoo waye nilu Ibadan lojo Wesidee, ojo kejidinlogun osu keta odun yii lawon adari yoo ti gba won wole.

Ogbeni Hamzat Folaranmi to je igbakeji alaga egbe SDP l'Osun, Enjinia Adetoye Ogungboyega to je alaga won n'Iwo-Oorun Osun, Pasito Tunde Hamzat to je akowe-owo, Alhaji Musibau Shittu to je akapo, Alhaja Iyabo Oyedele to je olori awon obinrin ati Lekan Obisakin to je akowe feto irorun awon omo egbe ni won yoo saaju awon omo egbe to ku lo sinu egbe PDP lojo naa.

Lara awon ti won tun ti fife han lati darapo mo egbe PDP ni Emiola Fakeye lati ekun idibo Guusu Ijesa, Alhaja Yekini Tawakalitu lati Iwo, Sooko Elugbaju Kemade lati Ife, Sola Ayandinrin lati Osogbo/Olorunda ati Adekunle Adeoye lati Ayedaade.

Awon yooku ni Kanmi Adelani lati Egbedore, Alhaji Badiru Raheem lati Boluwaduro, Alhaji Kamil Buhari lati Ejigbo, Musbau Salau to je akowe SDP, Taofeek Yusuf ati Rahmon Bakare lati Ejigbo.

Bakan naa ni awon alaga egbe lati ijoba ibile Ayedire, Iwo, Ayedaade, Ariwa Ede, Guusu Ede, Egbedore, Boluwaduro, Ifelodun, Atakunmosa, Osogbo, Olorunda, Obokun ati Boripe naa yoo ko awon omo egbe won sodi lo sinu egbe PDP lojo naa.

No comments:

Post a Comment