Aje o! Ara san pa maalu metadinlogun niluu Iba


Kayeefi lọrọ ara nla kan to ṣan ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ana si n jẹ fawọn eeyan Gaa Eleesun niluu Iba.

Ilu Iba lo wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi Baalẹ Fulani ilu naa, Oloye Jimọh Sọliu ṣe sọ fun Alaroye, lẹyin ti wọn ti ko awọn maalu ọhun jẹ, ti wọn si ti pada si Gaa ni ara nla naa ṣan, to si pa maalu mẹtadinlogun ati aguntan meji loju ẹsẹ.

Koda, jinnijinni ara naa kọlu diẹ lara awọn fulani nibẹ, to si jẹ pe ileewosan lo gba wọn nitẹẹ.

Oloye Jimọh ni iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹlẹ ri latigba toun ti deluu naa ati pe amuwa Ọlọrun lawọn ka gbogbo rẹ si.


No comments:

Post a Comment