O n rugbo bọ l'Ọṣun o! Awon omo egbe APC ni afi dandan ki Oshiomole yọ Famoodun nipo alaga


Ti awon alakoso egbe oselu APC lorileede yii ko ba tete wa nnkan se si rogbodiyan to n sele ninu egbe naa nipinle Osun bayii, afaimo ki won ma padanu Osun sowo egbe oselu alatako.



Eleyi ko seyin bi awon lookolooko ninu egbe APC l'Osun se n pariwo pe ki won yọ alaga, Omooba Gboyega Famoodun latari oniruuru iwa ti won fesun kan an pe o n hu.

Awon eeyan ohun, nipase agbenuso won, Alhaji Nurain Oladimeji salaye pe opolopo igbese ti egbe n gbe lo je pe Famodun nikan lo maa n da gbe e, ati pe ko si ọwọ fun awon agbaagba mọ ninu egbe.

Baba yii fi kun oro re pe latigba ti Famodun ti di alaga egbe l'Osun ni ko ti si idagbasoke kankan fun egbe, dipo bee, se ni won tun fidi remi ninu ibo to wa niha Iwo-oorun Osun lodun to koja.

O ni ọtọ ni nnkan ti iwe ofin egbe so, ọtọ si ni Famodun yoo se, idi niyii ti ko fi si ife ati isokan laarin awon omo egbe latigba to ti di alaga won.

Alhaji Nurain ni iyalenu lo je pe Famodun ko leta kan laipe yii loruko gbogbo awon adari egbe l'Osun laiso fun enikeni, o si mu leta naa lo solu ile egbe l'Abuja lati si pe ilana idibo gbangba-lasa-ta (direct primary) lawon omo egbe fe l'Osun, eleyii ti won ni iro to jinna si ootọ ni.

O ni eleyii fi han pe magomago kan wa ti Famodun atawon isomogbe re kan fee se ninu idibo piramari ti yoo waye lojo kokandinlogun osu keje ti a wa yii, eleyii ti won ni o lewu fegbe naa nitori o le mu won padanu Osun ninu idibo gbogbogbo.

Alhaji Nurain wa ke si alaga apapo egbe naa lorileede yii, Adams Oshiomole lati yọ Omooba Famoodun nipo gege bii alaga nipinle Osun nitori pe o ti huws tako ibura to bu nigba ti won yan an lati mase gbe si enikeni leyin, o ni ko seni ti ko mo pe Famoodun ni oludije kan pataki lokan to n sise fun laarin awon ti won n dupo gomina lowolowo bayii.

Bakan naa ni egbe kan ti kii se tijoba, Osun Sunrise nipase aare ati akowe won, Samuel Ariyibi ati Fatai Salaam so pe pelu bi nnkan se n lo ninu egbe APC Osun bayii, ko daju pe won setan lati wa nijoba ju osu kokanla odun yii lo.

Osun Sunrise ni iwa tinu-mi-ni-n-o-se ti Famoodun n hu fi han pe se lo fe ki egbe oselu alatako gbajoba mo Gomina Aregbesola lowo.

No comments:

Post a Comment