Iriri mi ninu oselu yoo ran mi lowo lati da ogo to ti sonu l'Osun pada - Adeniji


Okan lara awon to fee dije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu PDP, Enjinia Jide Adeniji ti so pe ti won ba gba oun laaye lati depo naa, imupadabosipo ti ko legbe ni yoo ba ipinle Osun.




Ninuu leta ti Adeniji fi ranse lati fi erongba re han fun awon adari egbe l'Osun pe oun nife lati dije dupo gomina ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii lo ti so pe ni gbogbo ona loun ti ye fun ipo naa.

O ni ise takuntakun toun se sin orileede yii nijoba ipinle ati ti apapo lailabawon pelu iriri oun ninu oselu je eri fun awon erongba olokanojokan toun ni lati fi mu igbesi aye iderun ba awon eeyan ipinle Osun.

Adeniji, eni to je omobibi ilu Ila to si tun ti figba kan je adari nileese ijoba apapo to n satunse awon ojuupopo ni isejoba oun yoo da ogo isejoba rere, ise agbe lona irorun, bibowo fun ofin ati igbedide okoowo pada sipinle Osun.

O ni eka marun nijoba oun yoo mojuto, eleyii toun pe oruko re ni SHARE. O ni oun yoo mojuto oro aabo, ilegbee, ise agbe, idagbasoke igberiko ati eto eko lokunkundun toun ba di gomina ipinle Osun.

Bakan naa lo ni oun ko nii koyan awon lobaloba kere ninu isejoba oun rara nitori pe ijoba alakoyawo loun n mu bo l'Osun.

No comments:

Post a Comment