Idi ti a fi kuro ninu egbe oselu SDP l'Osun - Awon Koseemani


Oke aimoye awon omo egbe oselu Social Democratic Party (SDP) nipinle Osun ni won ti digba-dagbon won bayii nimurasile lati darapo mo egbe oselu PDP.

Awon oloselu ti won ti laami-laaka lagbegbe won ohun ni won pe ara won ni Koseemani Group, won si je ida ogorin ninu ogorun-un awon omo egbe SDP nipinle yii.

Awon eeyan yii ni won pawopo di ibo to le legberun lona aadofa fun Otunba Iyiola Omisore labe abe SDP lasiko idibo gomina to waye koja l'Osun.

Sugbon ni bayii, latari ohun ti won sapejuwe gege bii iwa imotara-eni nikan ati ijora-eni loju ti oludije ipo gomina fegbe naa n hu si won, won pinnu lati darapo mo egbe oselu PDP.

Lasiko ipade itagbangba egbe PDP niha Iwo-oorun Guusu orileede yii, eleyii ti yoo waye nilu Ibadan lojo Wesidee, ojo kejidinlogun osu keta odun yii lawon adari yoo ti gba won wole.

Ogbeni Hamzat Folaranmi to je igbakeji alaga egbe SDP l'Osun, Enjinia Adetoye Ogungboyega to je alaga won n'Iwo-Oorun Osun, Pasito Tunde Hamzat to je akowe-owo, Alhaji Musibau Shittu to je akapo, Alhaja Iyabo Oyedele to je olori awon obinrin ati Lekan Obisakin to je akowe feto irorun awon omo egbe ni won yoo saaju awon omo egbe to ku lo sinu egbe PDP lojo naa.

Lara awon ti won tun ti fife han lati darapo mo egbe PDP ni Emiola Fakeye lati ekun idibo Guusu Ijesa, Alhaja Yekini Tawakalitu lati Iwo, Sooko Elugbaju Kemade lati Ife, Sola Ayandinrin lati Osogbo/Olorunda ati Adekunle Adeoye lati Ayedaade.

Awon yooku ni Kanmi Adelani lati Egbedore, Alhaji Badiru Raheem lati Boluwaduro, Alhaji Kamil Buhari lati Ejigbo, Musbau Salau to je akowe SDP, Taofeek Yusuf ati Rahmon Bakare lati Ejigbo.

Bakan naa ni awon alaga egbe lati ijoba ibile Ayedire, Iwo, Ayedaade, Ariwa Ede, Guusu Ede, Egbedore, Boluwaduro, Ifelodun, Atakunmosa, Osogbo, Olorunda, Obokun ati Boripe naa yoo ko awon omo egbe won sodi lo sinu egbe PDP lojo naa.

Se ni Wasiu bo lara torotoro nibi to ti fee ji irinse IBEDC n'Ilesa

Ole ni okunrin kan to pe oruko ara re ni Wasiu Ibrahim fe ja nidi ero amunawa ti ileese IBEDC, sugbon idajo ojiji lo ba pade nibe.

Lagbegbe Araromi loju-ona Ilesa si Akure nisele naa ti sele lose to koja.

Se ni ina sẹyọ lara awon waya kan nibe, to si bo Wasiu lara torotoro, awon eeyan agbegbe naa ni won fa a le awon olopa lowo ko to di pe awon yen gbe e lo sileewosan funtoju.

Leyin ti ara re bale ni won gba oro enu re sile, o si jewo pe se loun fe ji awon nnkan kan lara ero amunawa ohun.

Komisanna olopa nipinle Osun, Johnson Babatunde Kokumo ti safihan omokunrin naa, laipe ni yoo foju-bale ejo.

N'Ilesa, Seun ni ki orebinrin re lọ sẹyun, niyen ba gun un pa

Ileese olopa ipinle Osun ti bere iwadi lori oro omobinrin kan to gun orekunrin re pa nilu Ilesa lale ana.
Orekunrin naa, Seun la gbo pe o ti feyawo, to si ti bimo meji, sugbon ti oun atomobinrin kan tun n yan ara won lale.
Omobinrin yii la gbo pe o loyun, sugbon ti Seun n be e pe ko lo seyun naa, o si yari kanle pe oun ko seyun.
Asiko ti won n fa oro naa lowo lo fa fooki yo, to si gun Seun nikun pelu agbara, ibi tiyen ti n japoro iku lowo lo tun ti bere si gun un, titi to fi subu lule, to si ku patapata.
Omobinrin yen ti wa lakolo awon olopa bayii.

Nitori obinrin, Emmanuel gba Otunba looka n'Ipetumodu, ibe lo ku si

Okunrin olode kan, Emmanuel la gbo pe o gba enikeji re, Fatai Otunba looka lasiko ede-aiyede kan to sele laarin won.

Emmanuel lo fesun kan Otunba pe o n yan iyawo oun lale, aarin oru lo si lo sile re lagbegbe Sooko nilu Ipetumodu lale ojo satide to koja.

Leyin iseju die ti won ti n fa oro naa mo ara won lowo, ti awon olode bii merin ti won tun wa nibe ko gba kawon aradugbo ba won pari e, ni Emmanuel fa ooka yo, osi fi gba Fatai, ibe lo si ku si.

Ni bayii, won ti gbe oku re lo sileewosan Jenera nilu Ileefe, awon olopa Ipetumodu ti mu Emmanuel lo si olu ileese won l'Osogbo.

Iro ni o, awa o sa kuro l'Osun o - Akowe awon Fulani

Akowe awon fulani nipinle Osun, Alfa Saheed
Hussein ti so pe ko si ooto kankan ninu iroyin kan to n lo kaakiri bayii pe awon fulani ti n sa kuro l'Osun nitori isele ara to san pa maalu metadinlogun nirole ojo Fraide.

Alfa Hussein ni ko si ki iru amuwa Olorun beyen ma maa sele leekookan, sugbon to ba sele, awon ko le tori re kuro nibi tawon ti n gbe lati opolopo odun seyin.

O ni digbi lawon wa kaakiri nipinle Osun nitori ibagbepo awon pelu awon araalu je ti alaafia.

Aje o! Ara san pa maalu metadinlogun niluu Iba


Kayeefi lọrọ ara nla kan to ṣan ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ana si n jẹ fawọn eeyan Gaa Eleesun niluu Iba.

Ilu Iba lo wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi Baalẹ Fulani ilu naa, Oloye Jimọh Sọliu ṣe sọ fun Alaroye, lẹyin ti wọn ti ko awọn maalu ọhun jẹ, ti wọn si ti pada si Gaa ni ara nla naa ṣan, to si pa maalu mẹtadinlogun ati aguntan meji loju ẹsẹ.

Koda, jinnijinni ara naa kọlu diẹ lara awọn fulani nibẹ, to si jẹ pe ileewosan lo gba wọn nitẹẹ.

Oloye Jimọh ni iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ṣẹlẹ ri latigba toun ti deluu naa ati pe amuwa Ọlọrun lawọn ka gbogbo rẹ si.


O ga o! N'Ileefe, awon oku tun jona nile igbokusi


O kere tan, oku mẹwa ni ina jo nilee igbokupamosi to je ti eka Anatomy nileewe Obafemi Awolowo University, Ileefe.

Laago merin aabo idaji oni nisele ina ohun, eleyii ti enikeni ko le so ohun to fa a, be sile.

Alukooro funleese olopaa ipinle Osun, Folasade Odoro fidi isele naa mule, o si so pe iwadi ti bere lori e.