Owo-ori: Aregbesola fee gbe awon onigbese lo sile ejo

Ijoba ipinle Osun ti setan lati gbe gbogbo awon ileese nlanla ati ileese aladani ti won je obitibiti gbese owo-ori lo sile ejo.




Lara awon ileese naa ni NTA lle-Ife ( N6, 734,886), Globacom Nigeria Limited (N7,600,595), O.A.U (N1,844,770) SAMMYA NIGERIA LIMITED (N5,002,567), WETLAND CONSTRUCTION NIGERIA LIMITED (#8,686,336), 9 Mobiles (N 882,458,475).

Awon to ku ni Nigeria Custom Services (# 111,221,381), Nigeria Security and Civil Defense Corps (N128,289,909), Nigeria Prison Services (N44, 567, 867), Center for Energy Research and Development (N 42, 393,130), LAPO AGRIC DEVELOPMENT (N 7,078,313) ati KABASON GLOBAL INVESTMENT LIMITED( N 13, 566, 399).

Gege bi oludamodan pataki fun gomina lori ork owo-ori ati ipawowole labenu, Ogbeni Olugbenga Akano se so, gbogbo igbiyanju lati ba awon onigbese naa soro nitubinnubi lo ja si pabo.

Akano ni ijoba ti setan bayii lati gbe gbogbo won lo sile ejo ti won ba kuna lati san gbogbo owo ti won je laarin ojo meje pere.

Apapo owo-ori ti won je ohun, gege bi Akano se so je bilioonu mejila ataabo naira.

Ninu oro tie, komisanna feto iroyin, Adelani Baderinwa ni o nira funjoba lati pawo wole labenu lai rogboku le owo to n wole lati odo ijoba apapo.

O ni enikeni to ba kuna lati san owo ori gbodo mo pe oun ti se lodi si agbekale ofin, eleyii to ni o nijiya labe ofin iwa odaran lorileede yii.

No comments:

Post a Comment