Awon eeyan ilu Moro ati Yakoyo kọju ija si ara won nitori idajọ ilẹ

Ara ko rokun, ara o rọ adiye lowolowo bayii nilu Moro ati Yakooyo nijoba ibile Ariwa Ife.

Koda, Iroyin kan ti a ko le fidi re mule bayii so pe eeyan meta lo ti jẹpe Olorun, nigba ti opolopo si farapa yannayanna.

Lakọlakọ ni ibon n dun, ti ko si si ifokanbale fun enikeni. Idajo kan la gbo pe awon eeyan ilu Yakoyo gba nile ejo giga ilu Ife laarin ose yii.

Idajo yii lo fun won lase lati lo gba awon ile won tawon eeyan ilu Moro ti gbẹsẹ le.

A gbo pe won lo ba DPO ileese olopa ilu Moro lati fun won lolopa kawon le samuse idajo kootu naa, sugbon iyen so fun won pe komisanna olopa lo lagbara lati se bee.

Laaro oni, lawon eeyan ilu Yakoyo bo sita pelu atileyin baba oloselu kan nilu naa, gege bii aheso ti a gbo, baba yii lo fun won ni sọja kan to n tele won kaakiri awon agbegbe ti ilu Moro ti tase agẹrẹ wonu ile won.

Awon eeyan ilu Moro pe won nija lori nnkan ti won n se, a gbo pe inu bi soja naa, o si sina ibon bole, bayii ni wahala bere lati aaro.

Alukoro ileese olopa ipinle Osun fidi isele naa mule, sugbon won ko le so boya enikeni gbemi mi ninu isele naa.


No comments:

Post a Comment