Nitori ẹyin oṣiṣẹ ijọba ni mo ṣe n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ APC - Omiṣore

Igbakeji gomina tẹlẹ nipinle Osun, Otunba Iyiola Omisore ti so pe lati le maa pariwo igbayegbadun awon osise ijoba nipinle Osun si eti Gomina Gboyega Oyetola loun se gba lati fi egbe SDP sile, darapo mo egbe APC.

Omisore, eni to dupo gomina ipinle Osun lodun to koja labe asia egbe oselu SDP, ko too di pe o sise po pelu egbe APC lasiko atundi ibo salaye oro yii nile rẹ niluu Ileefe.

O ni oun ko fe ki awon araalu, paapaa awon osise ijoba atawon osisefeyinti ri igbese oun lati sise po pelu APC bii pe se loun fi ọbẹ ẹyin jẹ won niṣu.

Omisore ni okan pataki lara erongba egbe oselu SDP latigba ti won ti da a sile ni lati mu aye rorun fun awon osise ijoba, oun si gbe e siwaju egbe PDP ati APC lasiko ti won nilo iranlowo oun fun atundi ibo losu kesan odun to koja.

O ni egbe oselu APC nikan lo setan lati gba ọrọ naa yewo, ti won si seleri lati mu oro awon osise ijoba pelu awon osisefeyinti lokunkundun.

Otunba wa fi da gbogbo awon osisefeyinti atawon osise ijoba loju pe iya kankan ko ni je won labe isejoba Gomina Oyetola, o ni oogun oju won ko nii gbe, bee nijoba ko nii fi eto won dun won.

No comments:

Post a Comment