E ka ohun to sele si Yetunde, osere tiata to n jale, nigba to dele-ejo



Adajo kootu majisreeeti kan to wa n'Ikeja, Onidajo Sule Amzat, ti pase pe ki won fi osere tiata Yoruba nni, Yetunde Akilapa, ti won mu fun esun ole jija pamo digba ti yoo ri owo itanran egberun lona igba naira ati oniiduro meji ti won ni ko mu wa.


Lasiko ti igbejo naa n lo lowo ni olopaa agbefoba, Ogbeni Benson Emuerhi,  so pe ojo ketadinlogbon, osu kefa, odun yii lowo te Yetunde lasiko to fee ja okunrin kan toruko e n je Adeboye Lamidi lole.

Gege bi iwe ipejo naa se wi, kokoro aramanda to wa lowo Yetunde lo fi silekun ile okunrin naa, to wa lopopona Murairu,  Shangisha, nipinle Eko,  eyi to lodi sofin ipinle Eko, dukia tiye re je milionu meje ni won so pe Yetunde to n gbe lojule keje, opopona Aladela, Ikosi-Ketu fee ji ko, kowo to te e. 

Adajo  fun Yetunde eni odun mejilelogbon lanfaani beeli egberun lona igba naira pelu oniiduro meji ti won gbodo je osise ijoba, ti won si niwe eri owo ori odun meji lowo, bee lo pase pe ki won si fi osere yii pamo digba ti yoo rowo beeli e yii san.

Ojo kejilelogun osu, kokanla, odun yii, ladajo sun ojo igbejo mi-in si.

No comments:

Post a Comment